1. LI akoko na ni Merodaki-baladani, ọmọ Baladani, ọba Babiloni, rán iwe ati ọrẹ si Hesekiah: nitori o ti gbọ́ pe o ti ṣaisàn, o si ti sàn.
2. Inu Hesekiah si dùn si wọn, o si fi ile iṣura hàn wọn, fadaka, ati wura, ati nkan olõrun didùn, ati ikunra iyebiye, ati ile gbogbo ìhamọra rẹ̀, ati ohun gbogbo ti a ri ninu iṣura rẹ̀: kò si si nkankan ti Hesekiah kò fi hàn wọn ninu ile rẹ̀, tabi ni ijọba rẹ̀.