Isa 38:4-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Isaiah wá, wipe,

5. Lọ, si wi fun Hesekiah pe, Bayi ni Oluwa, Ọlọrun Dafidi baba rẹ wi, mo ti gbọ́ adura rẹ, mo ti ri omije rẹ: kiyesi i emi o fi ọdun mẹ̃dogun kún ọjọ rẹ.

6. Emi o si gbà ọ ati ilu yi lọwọ ọba Assiria: emi o si dãbò bò ilu yi.

7. Eyi yio sì jẹ àmi fun ọ lati ọdọ Oluwa wá, pe, Oluwa yio ṣe nkan yi ti o ti sọ;

8. Kiyesi i, emi o tún mu ìwọn òjiji ti o ti sọkalẹ lara agogo-õrùn Ahasi pada ni ìwọn mẹwa. Bẹ̃ni õrun pada ni ìwọn mẹwa ninu ìwọn ti o ti sọkalẹ.

9. Iwe Hesekiah ọba Juda, nigbati o fi ṣaisàn, ti o si sàn ninu aisàn rẹ̀:

10. Mo ni, ni ìke-kuro ọjọ mi, emi o lọ si ẹnu-ọnà isà-okú; a dù mi ni iyokù ọdun mi.

11. Mo ni, emi kì yio ri Oluwa, ani Oluwa, ni ilẹ alãyè: emi kì yio ri enia mọ lãrin awọn ti ngbé ibi idakẹ.

12. Ọjọ ori mi lọ, a si ṣi i kuro lọdọ mi bi àgọ olùṣọ agutan: mo ti ké ẹmi mi kuro bi ahunṣọ: yio ké mi kuro bi fọ́nran-òwu tinrin: lati ọ̀san de oru ni iwọ o mu mi de òpin mi.

13. Mo ṣirò titi di òwurọ, pe, bi kiniun, bẹ̃ni yio fọ́ gbogbo egungun mi; lati ọ̀san de oru ni iwọ o mu mi de òpin mi.

14. Bi akọ̀ tabi alapandẹ̀dẹ, bẹ̃ni mo dún; mo kãnu bi oriri: ãrẹ̀ mu oju mi fun iwòke: Oluwa, ara nni mi: ṣe onigbọwọ mi.

15. Kili emi o wi? o ti sọ fun mi, on tikalarẹ̀ si ti ṣe e: emi o ma lọ jẹjẹ fun gbogbo ọdun mi ni kikorò ọkàn mi.

Isa 38