Isa 38:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI ọjọ wọnni Hesekiah ṣaisàn de oju ikú. Woli Isaiah ọmọ Amosi si wá sọdọ rẹ̀, o si wi fun u pe, Bayi ni Oluwa wi, Palẹ ile rẹ mọ́: nitori iwọ o kú, o ki yio si yè.

2. Nigbana ni Hesekiah yi oju rẹ̀ si ogiri, o si gbadura si Oluwa.

3. O si wipe, Nisisiyi, Oluwa, mo bẹ̀ ọ, ranti bi mo ti rìn niwaju rẹ li otitọ ati pẹlu aiya pipé, ati bi mo si ti ṣe eyiti o dara li oju rẹ. Hesekiah si sọkún pẹrẹ̀pẹrẹ̀.

4. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Isaiah wá, wipe,

5. Lọ, si wi fun Hesekiah pe, Bayi ni Oluwa, Ọlọrun Dafidi baba rẹ wi, mo ti gbọ́ adura rẹ, mo ti ri omije rẹ: kiyesi i emi o fi ọdun mẹ̃dogun kún ọjọ rẹ.

6. Emi o si gbà ọ ati ilu yi lọwọ ọba Assiria: emi o si dãbò bò ilu yi.

7. Eyi yio sì jẹ àmi fun ọ lati ọdọ Oluwa wá, pe, Oluwa yio ṣe nkan yi ti o ti sọ;

8. Kiyesi i, emi o tún mu ìwọn òjiji ti o ti sọkalẹ lara agogo-õrùn Ahasi pada ni ìwọn mẹwa. Bẹ̃ni õrun pada ni ìwọn mẹwa ninu ìwọn ti o ti sọkalẹ.

9. Iwe Hesekiah ọba Juda, nigbati o fi ṣaisàn, ti o si sàn ninu aisàn rẹ̀:

10. Mo ni, ni ìke-kuro ọjọ mi, emi o lọ si ẹnu-ọnà isà-okú; a dù mi ni iyokù ọdun mi.

Isa 38