5. Iwọ wi pe, Mo ni, (ṣugbọn ọ̀rọ ète lasan ni nwọn) emi ni ìmọ ati agbara fun ogun jija: njẹ tani iwọ tilẹ gbẹkẹle ti iwọ fi nṣọ̀tẹ si mi?
6. Wò o, iwọ gbẹkẹle ọpá iyè fifọ́ yi, le Egipti; eyiti bi ẹnikẹni ba fi ara tì, yio wọnu ọwọ́ rẹ̀, yio si gún u: bẹ̃ni Farao ọba Egipti ri si gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e.
7. Ṣugbọn bi iwọ ba wi fun mi pe, Awa gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun wa: on kọ́ ẹniti Hesekiah ti mu ibi giga rẹ̀ wọnni, ati pẹpẹ rẹ̀, wọnni kuro, ti o si wi fun Juda ati Jerusalemu pe, ẹnyin o ma sìn niwaju pẹpẹ yi?
8. Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, mu ohun-iyàn wá fun oluwa mi ọba Assiria, emi o si fun ọ li ẹgbã ẹṣin, bi iwọ nipa tirẹ ba le ni enia to lati gùn wọn.