Isa 36:11-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Nigbana ni Eliakimu ati Ṣebna ati Joa wi fun Rabṣake pe, Mo bẹ̀ ọ, ba awọn ọmọ-ọdọ rẹ sọ̀rọ li ède Siria, nitori awa gbọ́: má si ṣe ba wa sọ̀rọ li ède Ju, li eti awọn enia ti o wà lori odi.

12. Ṣugbọn Rabṣake wipe, Oluwa mi ha rán mi si oluwa rẹ lati sọ ọ̀rọ wọnyi? kò ha ran mi sọdọ awọn ọkunrin ti o joko lori odi, ki nwọn ki o le ma jẹ igbẹ́ ara wọn, ki nwọn si ma mu ìtọ ara wọn pẹlu nyin?

13. Nigbana ni Rabṣake duro, o si fi ohùn rara kigbe li ède awọn Ju, o si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ ọba nla, ọba Assiria.

14. Bayi ni ọba na wi, pe, Ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah tàn nyin jẹ: nitori on kì o lè gbà nyin.

15. Ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah ki o mu nyin gbẹkẹle Oluwa, wipe, Ni gbigbà Oluwa yio gbà wa, a ki o fi ilu yi le ọba Assiria lọwọ.

Isa 36