Isa 34:7-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ati awọn agbanrere yio bá wọn sọkalẹ wá, ati awọn ẹgbọ̀rọ malu pẹlu awọn akọ malu; ilẹ wọn li a o fi ẹ̀jẹ rin, a o si fi ọ̀rá sọ ekuru wọn di ọlọ́ra.

8. Nitori ọjọ ẹsan Oluwa ni, ati ọdun isanpadà, nitori ọ̀ran Sioni.

9. Odò rẹ̀ li a o si sọ di ọ̀dà, ati ekuru rẹ̀ di imi-õrun, ilẹ rẹ̀ yio si di ọ̀dà ti njona.

10. A kì o pa a li oru tabi li ọsan; ẹ̃fin rẹ̀ yio goke lailai: yio dahoro lati iran de iran; kò si ẹnikan ti yio là a kọja lai ati lailai.

11. Ṣugbọn ẹiyẹ ofú ati àkala ni yio ni i; ati owiwi ati iwò ni yio ma gbe inu rẹ̀: on o si nà okùn iparun sori rẹ̀, ati okuta ofo.

12. Niti awọn ijoye rẹ̀ ẹnikan kì yio si nibẹ ti nwọn o pè wá si ijọba, gbogbo awọn olori rẹ̀ yio si di asan.

13. Ẹgún yio si hù jade ninu ãfin rẹ̀ wọnni, ẹgún ọ̀gan ninu ilú olodi rẹ̀: yio jẹ ibugbé awọn dragoni, ati agbalá fun awọn owiwi.

14. Awọn ẹran ijù ati awọn ọ̀wawa ni yio pade, ati satire kan yio ma kọ si ekeji rẹ̀; iwin yio ma gbe ibẹ̀ pẹlu, yio si ri ibí isimi fun ara rẹ̀.

Isa 34