Isa 32:15-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Titi a o fi tú Ẹmi jade si wa lara lati oke wá, ati ti aginju yio fi di ilẹ eléso, ti a o si kà ilẹ eleso si bi igbo.

16. Nigbana ni idajọ yio ma gbe aginju; ati ododo ninu ilẹ eleso.

17. Iṣẹ ododo yio si jẹ alafia, ati eso ododo yio jẹ idakẹjẹ on ãbo titi lai.

18. Awọn enia mi yio si ma gbe ibugbe alafia, ati ni ibugbe idaniloju, ati ni ibi isimi iparọrọ;

19. Ṣugbọn yio rọ̀ yìnyín, nigbati igbó nṣubu lulẹ; ati ni irẹlẹ a o rẹ̀ ilu na silẹ.

20. Alabukun fun ni ẹnyin ti nfọ̀nrugbìn niha omi gbogbo, ti nrán ẹṣẹ malu ati ti kẹtẹkẹtẹ jade sibẹ.

Isa 32