Isa 32:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. KIYESI i, ọba kan yio jẹ li ododo, awọn olori yio fi idajọ ṣe akoso.

2. Ẹnikan yio si jẹ bi ibi isápamọ́ kuro loju ẹfũfu, ati ãbo kuro lọwọ ijì; bi odo-omi ni ibi gbigbẹ, bi ojiji apata nla ni ilẹ gbigbẹ.

3. Oju awọn ẹniti o riran kì yio ṣe baibai, ati eti awọn ti o ngbọ́ yio tẹ́ silẹ.

4. Ọkàn awọn oniwàduwàdu yio mọ̀ oye, ahọn awọn akolòlo yio sọ̀rọ kedere.

5. A kì yio tun pè alaigbọ́n ni ẹni-ọlá mọ, bẹ̃ni a kì yio pe ọ̀bàlújẹ́ ni ẹni pataki mọ.

Isa 32