9. Mu ara duro jẹ, ki ẹnu ki o yà nyin; ẹ fọ́ ara nyin loju, ẹ si fọju: nwọn mu amupara; ṣugbọn kì iṣe fun ọti-waini, nwọn nta gbọngbọ́n ṣugbọn kì iṣe fun ohun mimu lile.
10. Nitori Oluwa dà ẹmi õrun ijìka lù nyin, o si se nyin li oju: awọn wolĩ ati awọn olori awọn ariran nyin li o bò li oju.
11. Iran gbogbo si dabi ọ̀rọ iwe kan fun nyin ti a dí, ti a fi fun ẹnikan ti o mọ̀ ọ kà, wipe, Emi bẹ̀ ọ, kà eyi, ti o si wipe, emi kò le ṣe e; nitori a ti dí i.
12. A si fi iwe na fun ẹniti kò mọ̀ iwe, wipe, Emi bẹ̀ ọ, kà eyi, on si wipe, emi kò mọ̀ iwe.
13. Nitorina Oluwa wipe, Niwọ̀n bi awọn enia yi ti nfi ẹnu wọn fà mọ mi, ti nwọn si nfi etè wọn yìn mi, ṣugbọn ti ọkàn wọn jìna si mi, ti nwọn si bẹru mi nipa ilana enia ti a kọ́ wọn.
14. Nitorina, Kiye si i, emi o ma ṣe iṣẹ́ iyanu lọ lãrin awọn enia yi, ani iṣẹ iyanu ati ajeji: ọgbọ́n awọn ọlọgbọ́n wọn yio si ṣegbe, oye awọn amoye wọn yio si põra.
15. Egbe ni fun awọn ti nwá ọ̀na lati fi ipinnu buruburu wọn pamọ́ kuro loju Oluwa, ti iṣẹ wọn si wà li okunkun, ti nwọn si wipe, Tali o ri wa? tali o mọ̀ wa?
16. A, iyipo nyin! a ha le kà amọ̀koko si bi amọ̀: ohun ti a mọ ti ṣe lè wi fun ẹniti o ṣe e pe, On kò ṣe mi? ìkoko ti a mọ le wi fun ẹniti o mọ ọ pe, On kò moye?