15. Egbe ni fun awọn ti nwá ọ̀na lati fi ipinnu buruburu wọn pamọ́ kuro loju Oluwa, ti iṣẹ wọn si wà li okunkun, ti nwọn si wipe, Tali o ri wa? tali o mọ̀ wa?
16. A, iyipo nyin! a ha le kà amọ̀koko si bi amọ̀: ohun ti a mọ ti ṣe lè wi fun ẹniti o ṣe e pe, On kò ṣe mi? ìkoko ti a mọ le wi fun ẹniti o mọ ọ pe, On kò moye?
17. Kò ha ṣe pe ìgba diẹ kiun si i, a o sọ Lebanoni di ọgbà eleso, ati ọgbà eleso li a o kà si bi igbo?
18. Ati li ọjọ na awọn aditi yio si gbọ́ ọ̀rọ iwe nì, awọn afọju yio si riran lati inu owúsuwusù, ati lati inu okunkun.