Isa 26:16-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Oluwa, ninu wahala ni nwọn wá ọ, nwọn gbadura wúyẹ́wúyẹ́ nigbati ibawi rẹ wà lara wọn.

17. Gẹgẹ bi aboyun, ti o sunmọ akoko ibi rẹ̀, ti wà ni irora, ti o si kigbe ninu irora rẹ̀; bẹ̃li awa ti wà li oju rẹ, Oluwa.

18. Awa ti loyun, awa ti wà ni irora, o si dabi ẹnipe awa ti bi ẹfũfu; awa kò ṣiṣẹ igbala kan lori ilẹ, bẹ̃ni awọn ti ngbe aiye kò ṣubu.

19. Awọn okú rẹ yio yè, okú mi, nwọn o dide. Ẹ ji, ẹ si kọrin, ẹnyin ti ngbe inu ekuru: nitori ìri rẹ ìri ewebẹ̀ ni, ilẹ yio si sọ awọn okú jade.

20. Wá, enia mi, wọ̀ inu iyẹ̀wu rẹ lọ, si se ilẹkun rẹ mọ ara rẹ: fi ara rẹ pamọ bi ẹnipe ni iṣẹ́ju kan, titi ibinu na fi rekọja.

Isa 26