16. Oluwa, ninu wahala ni nwọn wá ọ, nwọn gbadura wúyẹ́wúyẹ́ nigbati ibawi rẹ wà lara wọn.
17. Gẹgẹ bi aboyun, ti o sunmọ akoko ibi rẹ̀, ti wà ni irora, ti o si kigbe ninu irora rẹ̀; bẹ̃li awa ti wà li oju rẹ, Oluwa.
18. Awa ti loyun, awa ti wà ni irora, o si dabi ẹnipe awa ti bi ẹfũfu; awa kò ṣiṣẹ igbala kan lori ilẹ, bẹ̃ni awọn ti ngbe aiye kò ṣubu.