Isa 26:10-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Bi a ba fi ojurere hàn enia buburu, kì yio kọ́ ododo: ni ilẹ iduroṣinṣin li on o hùwa aiṣõtọ, kì yio si ri ọlanla Oluwa.

11. Oluwa, ọwọ́ rẹ gbe soke, nwọn kì yio ri, ṣugbọn nwọn o ri, oju o si tì wọn nitori ilara wọn si awọn enia; nitõtọ, iná awọn ọta rẹ yio jẹ wọn run.

12. Oluwa, iwọ o fi idi alafia mulẹ fun wa: pẹlupẹlu nitori iwọ li o ti ṣe gbogbo iṣẹ wa fun wa.

13. Oluwa Ọlọrun wa, awọn oluwa miran lẹhin rẹ ti jọba lori wa: ṣugbọn nipa rẹ nikan li awa o da orukọ rẹ sọ.

14. Awọn okú, nwọn kì yio yè; awọn ti ngbe isà-okú, nwọn kì yio dide; nitorina ni iwọ ṣe bẹ̀ wọn wò ti o si pa wọn run, ti o si mu ki gbogbo iranti wọn parun.

15. Iwọ ti mu orilẹ-ède bi si i, Oluwa, iwọ ti mu orilẹ-ède bi si i; iwọ ti di ẹni-ãyin li ogo: iwọ ti sún gbogbo ãlà siwaju.

16. Oluwa, ninu wahala ni nwọn wá ọ, nwọn gbadura wúyẹ́wúyẹ́ nigbati ibawi rẹ wà lara wọn.

17. Gẹgẹ bi aboyun, ti o sunmọ akoko ibi rẹ̀, ti wà ni irora, ti o si kigbe ninu irora rẹ̀; bẹ̃li awa ti wà li oju rẹ, Oluwa.

Isa 26