2. Nitori iwọ ti sọ ilu kan di okiti; iwọ ti sọ ilu olodi di iparun: ãfin awọn alejo, kò jẹ ilu mọ́; a kì yio kọ́ ọ mọ.
3. Nitorina ni awọn alagbara enia yio yìn ọ li ogo, ilu orilẹ-ède ti o ni ibẹ̀ru yio bẹ̀ru rẹ.
4. Nitori iwọ ti jẹ agbara fun talaka, agbara fun alaini ninu iṣẹ́ rẹ̀, ãbo kuro ninu ìji, ojiji kuro ninu oru, nigbati ẹfũfu lile awọn ti o ni ibẹ̀ru dabi ìji lara ogiri.
5. Iwọ o mu ariwo awọn alejo rọlẹ, gẹgẹ bi oru nibi gbigbẹ; ani oru pẹlu ojiji awọsanma: a o si rẹ̀ orin-ayọ̀ awọn ti o ni ibẹ̀ru silẹ.