Isa 25:1-2 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA, iwọ li Ọlọrun mi; emi o gbe ọ ga, emi o yìn orukọ rẹ; nitori iwọ ti ṣe ohun iyanu; ìmọ igbani, ododo ati otitọ ni.

2. Nitori iwọ ti sọ ilu kan di okiti; iwọ ti sọ ilu olodi di iparun: ãfin awọn alejo, kò jẹ ilu mọ́; a kì yio kọ́ ọ mọ.

Isa 25