9. Oluwa awọn ọmọ-ogun ti pete rẹ̀, lati sọ irera gbogbo ogo di aimọ́, lati sọ gbogbo awọn ọlọla aiye di ẹ̀gan.
10. La ilẹ rẹ ja bi odò, iwọ ọmọbinrin Tarṣiṣi: àmure kò si mọ́.
11. O nà ọwọ́ rẹ̀ jade si oju okun, o mì awọn ijọba: Oluwa ti pa aṣẹ niti Kenaani, lati run agbàra inu rẹ̀.
12. On si wipe, Iwọ kò gbọdọ yọ̀ mọ, iwọ wundia ti a ni lara, ọmọbinrin Sidoni; dide rekọja lọ si Kittimu, nibẹ pẹlu iwọ kì yio ri isimi.
13. Wò ilẹ awọn ara Kaldea; awọn enia yi kò ti si ri, titi awọn ara Assiria tẹ̀ ẹ dó fun awọn ti ngbe aginju: nwọn kọ́ ile-iṣọ́ inu rẹ̀, nwọn si kọ́ ãfin inu rẹ̀; on si pa a run.
14. Hu, ẹnyin ọkọ̀ Tarṣiṣi: nitori a sọ agbara nyin di ahoro.