4. Ki oju ki o tì ọ, Iwọ Sidoni: nitori okun ti sọ̀rọ, ani agbara okun, wipe, Emi kò rọbi, bẹ̃ni emi kò bi ọmọ, bẹ̃li emi kò tọ́ ọdọmọkunrin dàgba, bẹ̃ni emi kò tọ́ wundia dàgba.
5. Gẹgẹ bi ihìn niti Egipti, bẹ̃ni ara yio ro wọn goro ni ihìn Tire.
6. Ẹ kọja si Tarṣiṣi; hu, ẹnyin olugbé erekùṣu.
7. Eyi ha ni ilu ayọ̀ fun nyin, ti o ti wà lati ọjọ jọjọ? ẹsẹ on tikara rẹ̀ yio rù u lọ si ọna jijìn rére lati ṣe atipó.