3. Ẹmi Egipti yio si rẹ̀wẹsi lãrin inu rẹ̀; emi o si pa ìmọ inu rẹ̀ run: nwọn o si wá a tọ̀ òriṣa lọ, ati sọdọ awọn atuju, ati sọdọ awọn ajẹ́, ati sọdọ awọn oṣó;
4. Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Awọn ara Egipti li emi o fi le oluwa onrorò li ọwọ́; ọba ti o muna yio ṣe akoso wọn.
5. Omi yio si buṣe li okun, a o si fi odò ṣofo, yio si gbẹ.
6. Odò yio si di rirùn; odò ãbo li a o sọ di ofo, ti a o si gbọ́n gbẹ; oko-odò ati iyè yio rọ.
7. Oko-tutù ni ipadò, li ẹnu odò, ati ohun gbogbo ti a gbìn sipadò, ni yio rọ, yio funka, kì yio si si mọ.
8. Awọn apẹja yio gbàwẹ pẹlu, ati gbogbo awọn ti nfì ìwọ li odò yio pohùnrére-ẹkun; ati awọn ti nda àwọn li odò yio sorikọ́.
9. Pẹlupẹlu awọn ti nṣiṣẹ ọ̀gbọ daradara, ati awọn ti nwun asọ-àla yio dãmu.
10. A o si fọ́ wọn ni ipilẹ rẹ̀, gbogbo awọn alagbàṣe li a o bà ni inu jẹ.