Isa 16:7-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nitorina ni Moabu yio hu fun Moabu, gbogbo wọn o hu: nitori ipilẹ Kir-haresi li ẹnyin o gbàwẹ; nitõtọ a lù wọn.

8. Nitori igbẹ́ Heṣboni rọ, ati àjara Sibma: awọn oluwa awọn keferi ti ke pataki ọ̀gbin rẹ̀ lu ilẹ, nwọn tàn de Jaseri, nwọn nrìn kakiri aginjù: ẹka rẹ̀ nà jade, nwọn kọja okun.

9. Nitorina emi o pohùnrére ẹkun, bi ẹkun Jaseri, àjara Sibma: emi o fi omije mi rin ọ, iwọ Heṣboni, ati Eleale: nitori ariwo nla ta lori èso-igi ẹ̃rùn rẹ, ati lori ikore rẹ.

10. A si mu inu-didun kuro, ati ayọ̀ kuro ninu oko ti nso eso ọ̀pọlọpọ; orin kì yio si si mọ ninu ọgbà-àjara, bẹ̃ni kì yio si ihó-ayọ̀ mọ: afọnti kì yio fọn ọti-waini mọ ninu ifọnti wọn, emi ti mu ariwo dá.

11. Nitorina inu mi yio dún bi harpu fun Moabu, ati ọkàn mi fun Kir-haresi.

12. Yio si ṣe, nigbati a ba ri pe ãrẹ̀ mú Moabu ni ibi giga, ni yio wá si ibi-mimọ́ rẹ̀ lati gbadura; ṣugbọn kì yio bori.

Isa 16