Isa 16:11-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Nitorina inu mi yio dún bi harpu fun Moabu, ati ọkàn mi fun Kir-haresi.

12. Yio si ṣe, nigbati a ba ri pe ãrẹ̀ mú Moabu ni ibi giga, ni yio wá si ibi-mimọ́ rẹ̀ lati gbadura; ṣugbọn kì yio bori.

13. Eyi li ọ̀rọ ti Oluwa ti sọ niti Moabu lati igbà na wá.

Isa 16