Isa 10:25-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Ṣugbọn niwọn igba diẹ kiun, irunú yio si tan, ati ibinu mi ninu iparun wọn.

26. Oluwa awọn ọmọ-ogun yio gbe paṣan kan soke fun u, gẹgẹ bi ipakupa ti Midiani ni apata Orebu: ati gẹgẹ bi ọgọ rẹ̀ soju okun, bẹ̃ni yio gbe e soke gẹgẹ bi iru ti Egipti.

27. Yio si ṣe li ọjọ na, ni a o gbe ẹrù rẹ̀ kuro li ejika rẹ, ati àjaga rẹ̀ kuro li ọrùn rẹ, a o si ba àjaga na jẹ ní ọrùn rẹ.

28. On de si Aiati, on ti kọja si Migroni; ni Mikmaṣi li on ko ẹrù-ogun rẹ̀ jọ si:

29. Nwọn ti rekọja ọ̀na na: nwọn ti wọ̀ ni Geba; Rama bẹ̀ru; Gibea ti Saulu sá.

30. Gbe ohùn rẹ soke, ọmọbinrin Gallimu: mu ki a gbọ́ ọ de Laiṣi, otòṣi Anatoti.

31. A ṣi Madmena nipo dà; awọn ara Gebimu ko ara wọn jọ lati sa.

32. Yio duro sibẹ ni Nobu li ọjọ na: on o si mì ọwọ́ rẹ̀ si oke giga ọmọbinrin Sioni, oke kekere Jerusalemu.

33. Kiyesi i, Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun yio fi ẹ̀ru wọ́n ẹka: ati awọn ti o ga ni inà li a o ke kuro, ati awọn agberaga li a o rẹ̀ silẹ.

34. On o si fi irin ke pantiri igbó lu ilẹ, Lebanoni yio si ṣubu nipa alagbara kan.

Isa 10