Nitorina bayi li Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ẹnyin enia mi ti ngbe Sioni, ẹ má bẹ̀ru awọn ara Assiria: on o fi ọgọ lù ọ, yio si gbe ọpa rẹ̀ soke si ọ, gẹgẹ bi iru ti Egipti.