Isa 10:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EGBE ni fun awọn ti npaṣẹ aiṣododo, ati fun awọn akọwe ti nkọ iwe ìka;

2. Lati yi alaini kuro ni idajọ, ati lati mu ohun ẹtọ kuro lọwọ talakà enia mi, ki awọn opo ba le di ijẹ wọn, ati ki wọn ba le jà alainibaba li ole!

3. Kili ẹnyin o ṣe lọjọ ibẹ̀wo, ati ni idahoro ti yio ti okere wá? tali ẹnyin o sá tọ̀ fun irànlọwọ? nibo li ẹnyin o si fi ogo nyin si?

4. Laisi emi nwọn o tẹ̀ ba labẹ awọn ara-tubu, nwọn o si ṣubu labẹ awọn ti a pa. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.

5. Egbe ni fun Assuri, ọgọ ibinu mi, ati ọ̀pa ọwọ́ wọn ni irúnu mi.

6. Emi o ran a si orilẹ-ède agabàgebe, ati fun awọn enia ibinu mi li emi o paṣẹ kan, lati ko ikogun, ati lati mu ohun ọdẹ, ati lati tẹ̀ wọn mọlẹ bi ẹrẹ̀ ni igboro.

7. Ṣugbọn on kò rò bẹ̃, bẹ̃ni ọkàn rẹ̀ kò rò bẹ̃; ṣugbọn o wà li ọkàn rẹ̀ lati parun ati lati ke orilẹ-ède kuro, ki iṣe diẹ.

8. Nitori o wipe, Ọba kọ awọn ọmọ-alade mi ha jẹ patapata?

9. Kalno kò ha dabi Karkemiṣi? Hamati kò ha dabi Arpadi? Samaria kò ha dabi Damasku?

10. Gẹgẹ bi ọwọ́ mi ti nà de ijọba ere ri, ere eyi ti o jù ti Jerusalemu ati ti Samaria lọ.

11. Bi emi ti ṣe si Samaria ati ere rẹ̀, emi kì yio ha ṣe bẹ̃ si Jerusalemu ati ere rẹ̀ bi?

Isa 10