3. Ṣe alabapin pẹlu mi ninu ipọnju, bi ọmọ-ogun rere Jesu Kristi.
4. Kò si ẹniti njàgun ti ifi ohun aiye yi dí ara rẹ̀ lọwọ, ki o le mu inu ẹniti o yàn a li ọmọ-ogun dùn.
5. Bi ẹnikẹni ba si njà, a kì dé e li ade, bikoṣepe o ba jà li aiṣe erú.
6. Àgbẹ ti o nṣe lãlã li o ni lati kọ́ mu ninu eso wọnni.
7. Gbà ohun ti emi nsọ rò; nitori Oluwa yio fun ọ li òye ninu ohun gbogbo.
8. Ranti Jesu Kristi, ti o jinde kuro ninu okú, lati inu irú-ọmọ Dafidi, gẹgẹ bi ihinrere mi,
9. Ninu eyiti emi nri ipọnju titi dé inu ìde bi arufin; ṣugbọn a kò dè ọ̀rọ Ọlọrun.