2. Si Timotiu, ọmọ mi olufẹ ọwọn: Ore-ọfẹ, ãnu, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Kristi Jesu Oluwa wa.
3. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun, ti emi nsìn lati ọdọ awọn baba mi wá ninu ẹri-ọkan funfun, pe li aisimi li emi nṣe iranti rẹ ninu adura mi,
4. T'ọsan t'oru li emi njaìyà ati ri ọ, ti mo nranti omije rẹ, ki a le fi ayọ̀ kún mi li ọkàn;
5. Nigbati mo ba ranti igbagbọ́ ailẹtan ti mbẹ ninu rẹ, eyiti o kọ́ wà ninu Loide iya-nla rẹ, ati ninu Eunike iya rẹ; mo si gbagbọ pe, o mbẹ ninu rẹ pẹlu.
6. Nitori idi eyi ni mo ṣe nran ọ leti pe ki iwọ ki o mã rú ẹ̀bun Ọlọrun soke eyiti mbẹ ninu rẹ nipa gbigbe ọwọ mi le ọ.