2. Tim 1:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. PAULU, Aposteli Kristi Jesu nipa ifẹ Ọlọrun, gẹgẹ bi ileri ìye ti mbẹ ninu Kristi Jesu,

2. Si Timotiu, ọmọ mi olufẹ ọwọn: Ore-ọfẹ, ãnu, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Kristi Jesu Oluwa wa.

3. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun, ti emi nsìn lati ọdọ awọn baba mi wá ninu ẹri-ọkan funfun, pe li aisimi li emi nṣe iranti rẹ ninu adura mi,

4. T'ọsan t'oru li emi njaìyà ati ri ọ, ti mo nranti omije rẹ, ki a le fi ayọ̀ kún mi li ọkàn;

2. Tim 1