2. Sam 8:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O SI ṣe, lẹhin eyi, Dafidi si kọlu awọn Filistini, o si tẹri wọn ba: Dafidi si gbà Metegamma lọwọ awọn Filistini.

2. O si kọlu Moabu, a si fi okùn tita kan diwọ̀n wọn, o si da wọn bu'lẹ; o si ṣe oṣuwọn okun meji ni iye awọn ti on o pa, ati ẹkún oṣuwọn okùn kan ni iye awọn ti yio dá si. Awọn ara Moabu si nsìn Dafidi, nwọn a si ma mu ẹbùn wá.

3. Dafidi si kọlu Hadadeseri ọmọ Rehobu, ọba Soba, bi on si ti nlọ lati gbà ilẹ rẹ̀ pada ti o gbè odo Eufrate.

4. Dafidi si gbà ẹgbẹrun kẹkẹ lọwọ rẹ̀, ati ẹ̃dẹgbẹrin ẹlẹṣin, ati ẹgbãwa awọn ẹlẹsẹ: Dafidi si ja gbogbo ẹṣin kẹkẹ́ wọn wọnni ni pátì, ṣugbọn o da ọgọrun kẹkẹ́ si ninu wọn.

5. Nigbati awọn ara Siria ti Damasku si wá lati ran Hadadeseri ọba Soba lọwọ, Dafidi si pa ẹgbãmọkanla enia ninu awọn ara Siria.

2. Sam 8