Dafidi ati gbogbo ile Israeli si ṣire niwaju Oluwa lara gbogbo oniruru elò orin ti a fi igi arere ṣe, ati lara duru, ati lara psalteri, ati lara timbreli, ati lara korneti, ati lara aro.