2. Sam 5:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. GBOGBO ẹya Israeli si tọ̀ Dafidi wá ni Hebroni, nwọn si wipe, Wõ, egungun rẹ ati ẹran ara rẹ li awa iṣe.

2. Ati nigba atijọ, nigbati Saulu fi jọba lori wa, iwọ ni ẹniti ima ko Israeli jade, iwọ ni si ma mu wọn bọ̀ wá ile: Oluwa si wi fun ọ pe, Iwọ o bọ́ Israeli awọn enia mi, iwọ o si jẹ olori fun Israeli.

3. Gbogbo agba Israeli si tọ ọba wá ni Hebroni, Dafidi ọba si ba wọn ṣe adehun kan ni Hebroni, niwaju Oluwa: nwọn si fi ororo yan Dafidi li ọba Israeli.

4. Dafidi si jẹ ẹni ọgbọn ọdun nigbati o jọba; on si jọba li ogoji ọdun.

5. O jọba ni Hebroni li ọdun meje on oṣu mẹfa lori Juda: o si jọba ni Jerusalemu li ọdun mẹtalelọgbọn lori gbogbo Israeli ati Juda.

2. Sam 5