6. Ọmọdekunrin na ti o sọ fun u wipe, Bi emi ti ṣe alabapade lori oke Gilboa, si wõ, Saulu fi ara tì ọkọ̀ rẹ̀, si wõ, kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin nlepa rẹ̀ kikan.
7. Nigbati o si yi oju wo ẹhin rẹ̀, ti o si ri mi, o pè mi, Emi si da a lohùn pe, Emi nĩ.
8. On si bi mi pe, Iwọ tani? Emi si da a lohùn pe, ara Amaleki li emi.
9. On si tun wi fun mi pe, Duro le mi, emi bẹ ọ ki o si pa mi: nitoriti wahala ba mi, ẹmi mi si wà sibẹ.
10. Emi si duro le e, mo si pa a, nitori ti o da mi loju pe, kò si tun le là mọ lẹhin igbati o ti ṣubu: emi si mu ade ti o wà li ori rẹ̀, ati ibọwọ ti o mbẹ li apa rẹ̀, emi si mu wọn wá ihinyi sọdọ oluwa mi.
11. Dafidi si di aṣọ rẹ̀ mu, o si fà wọn ya, gbogbo awọn ọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀ si ṣe bẹ̃ gẹgẹ.