2. Sam 1:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe lẹhin ikú Saulu, Dafidi si ti ibi iparun awọn ara Amaleki bọ̀, Dafidi si joko nijọ meji ni Siklagi;

2. O si ṣe ni ijọ kẹta, si wõ, ọkunrin kan si ti ibudo wá lati ọdọ Saulu; aṣọ rẹ̀ si faya, erupẹ si mbẹ li ori rẹ̀: o si ṣe, nigbati on si de ọdọ Dafidi, o wolẹ, o si tẹriba.

3. Dafidi si bi i lere pe, Nibo ni iwọ ti wá? o si wi fun u pe, Lati ibudo Israeli li emi ti sa wá.

4. Dafidi si tun bi lere wipe, Ọràn na ti ri? emi bẹ ọ, sọ fun mi. On si dahun pe, Awọn enia na sa loju ijà, ọ̀pọlọpọ ninu awọn enia na pẹlu si ṣubu; nwọn si kú, Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ si kú pẹlu.

5. Dafidi si bi ọmọdekunrin na ti o sọ fun u lere pe, Iwọ ti ṣe mọ̀ pe, Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ kú?

6. Ọmọdekunrin na ti o sọ fun u wipe, Bi emi ti ṣe alabapade lori oke Gilboa, si wõ, Saulu fi ara tì ọkọ̀ rẹ̀, si wõ, kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin nlepa rẹ̀ kikan.

7. Nigbati o si yi oju wo ẹhin rẹ̀, ti o si ri mi, o pè mi, Emi si da a lohùn pe, Emi nĩ.

8. On si bi mi pe, Iwọ tani? Emi si da a lohùn pe, ara Amaleki li emi.

9. On si tun wi fun mi pe, Duro le mi, emi bẹ ọ ki o si pa mi: nitoriti wahala ba mi, ẹmi mi si wà sibẹ.

2. Sam 1