2. Pet 3:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUFẸ, eyi ni iwe keji ti mo nkọ si nyin; ninu mejeji na li emi nrú inu funfun nyin soke nipa riran nyin leti:

2. Ki ẹnyin ki o le mã ranti ọ̀rọ ti a ti ẹnu awọn woli mimọ́ sọ ṣaju, ati ofin Oluwa ati Olugbala wa lati ọdọ awọn aposteli nyin:

3. Ki ẹ kọ́ mọ̀ eyi pe, nigba ọjọ ikẹhin, awọn ẹlẹgan yio de pẹlu ẹgan wọn, nwọn o mã rin nipa ifẹ ara wọn,

4. Nwọn o si mã wipe, Nibo ni ileri wíwa rẹ̀ gbé wà? lati igbati awọn baba ti sùn, ohun gbogbo nlọ bi nwọn ti wà rí lati ìgba ọjọ ìwa.

5. Nitori eyi ni nwọn mọ̃mọ ṣe aifẹ̃mọ, pe nipa ọ̀rọ Ọlọrun li awọn ọrun ti wà lati ìgba atijọ, ati ti ilẹ yọri jade ninu omi, ti o si duro ninu omi:

2. Pet 3