2. Pet 2:7-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. O si yọ Loti olõtọ, ẹniti ìwa wọbia awọn enia buburu bà ninu jẹ:

8. (Nitori ọkunrin olõtọ nì bi o ti ngbe ãrin wọn, ti o nri, ti o si ngbọ́, lojojumọ ni ìwa buburu wọn mba ọkàn otitọ rẹ̀ jẹ́):

9. Oluwa mọ̀ bi ã ti íyọ awọn ẹni ìwa-bi-Ọlọrun kuro ninu idanwo ati bi ã ti ípa awọn alaiṣõtọ ti a njẹ niya mọ dè ọjọ idajọ:

10. Ṣugbọn pãpã awọn ti ntọ̀ ara lẹhin ninu ifẹkufẹ ẽri, ti nwọn si ngàn awọn ijoye, awọn ọ̀yájú, aṣe-tinuẹni, nwọn kò bẹ̀ru ati mã sọ̀rọ ẹgan si awọn oloye.

11. Bẹni awọn angẹli bi nwọn ti pọ̀ ni agbara ati ipá tõ nì, nwọn kò dá wọn lẹjọ ẹ̀gan niwaju Oluwa.

12. Ṣugbọn awọn wọnyi, bi ẹranko igbẹ́ ti kò li ero, ẹranko ṣa ti a dá lati mã mu pa, nwọn nsọ̀rọ ẹgan ninu ọran ti kò yé wọn; a o pa wọn run patapata ninu ibajẹ ara wọn.

13. Nwọn o si jẹ ère aiṣododo, awọn ti nwọn kà a si aiye jijẹ lati mã jẹ adùn aiye li ọsán. Nwọn jẹ́ abawọn ati àbuku, nwọn njaiye ninu asè-ifẹ́ wọn nigbati nwọn ba njẹ ase pẹlu nyin;

2. Pet 2