12. Ṣugbọn awọn wọnyi, bi ẹranko igbẹ́ ti kò li ero, ẹranko ṣa ti a dá lati mã mu pa, nwọn nsọ̀rọ ẹgan ninu ọran ti kò yé wọn; a o pa wọn run patapata ninu ibajẹ ara wọn.
13. Nwọn o si jẹ ère aiṣododo, awọn ti nwọn kà a si aiye jijẹ lati mã jẹ adùn aiye li ọsán. Nwọn jẹ́ abawọn ati àbuku, nwọn njaiye ninu asè-ifẹ́ wọn nigbati nwọn ba njẹ ase pẹlu nyin;
14. Awọn oloju ti o kún fun panṣaga, ti kò si le dẹkun ẹ̀ṣẹ idá; ti ntàn awọn ọkàn ti kò fi ẹsẹ mulẹ jẹ: awọn ti nwọn ni ọkàn ti o ti fi ojukòkoro kọ́ra; awọn ọmọ ègún:
15. Nwọn kọ̀ ọ̀na ti o tọ́ silẹ, nwọn si ṣako lọ, nwọn tẹle ọ̀na Balaamu ọmọ Beori, ẹniti o fẹràn ère aiṣododo;
16. Ṣugbọn a ba a wi nitori irekọja rẹ̀: odi kẹtẹkẹtẹ fi ohùn enia sọ̀rọ, o si fi opin si were wolĩ na.
17. Awọn wọnyi ni kanga ti kò li omi, ikũku ti ẹfũfu ngbá kiri; awọn ẹniti a pa òkunkun biribiri mọ́ de tití lai.
18. Nitori igbati nwọn ba nsọ̀rọ ihalẹ asan, ninu ifẹkufẹ ara, nipa wọbia, nwọn a mã tan awọn ti nwọn fẹrẹ má ti ibọ tan kuro lọwọ ti nwọn wà ninu iṣina.