2. Pet 1:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. SIMONI Peteru, iranṣẹ ati Aposteli Jesu Kristi, si awọn ti o ti gbà irú iyebiye igbagbọ́ kanna pẹlu wa, ninu ododo Ọlọrun wa ati ti Jesu Kristi Olugbala:

2. Ki ore-ọfẹ ati alafia ki o mã bisi i fun nyin ninu ìmọ Ọlọrun, ati ti Jesu Oluwa wa,

3. Bi agbara rẹ̀ bi Ọlọrun ti fun wa li ohun gbogbo ti iṣe ti ìye ati ti ìwa-bi-Ọlọrun, nipa ìmọ ẹniti o pè wa nipa ogo ati ọlanla rẹ̀:

4. Nipa eyiti o ti fi awọn ileri rẹ̀ ti o tobi pupọ ti o si ṣe iyebiye fun wa: pe nipa iwọnyi ni ki ẹnyin ki o le di alabapin ninu ìwa Ọlọrun, nigbati ẹnyin bá ti yọ kuro ninu ibajẹ ti mbẹ ninu aiye nipa ifẹkufẹ.

5. Ati nitori eyi nã pãpã, ẹ mã ṣe aisimi gbogbo, ẹ fi ìwarere kún igbagbọ́, ati ìmọ kún ìwarere;

6. Ati airekọja kún ìmọ; ati sũru kún airekọja; ati ìwa-bi-Ọlọrun kún sũru;

7. Ati ifẹ ọmọnikeji kún ìwa-bi-Ọlọrun; ati ifẹni kún ifẹ ọmọnikeji.

2. Pet 1