1. BI Solomoni si ti pari adura igbà, iná bọ́ lati ọrun wá, o si jo ọrẹ sisun ati ẹbọ na run; ogo Oluwa si kún ile na.
2. Awọn alufa kò le wọ̀ inu ile Oluwa, nitori ogo Oluwa kún ile Oluwa.
3. Gbogbo awọn ọmọ Israeli si ri bi iná na ti bọ́ silẹ, ati ogo Oluwa sori ile na, nwọn doju wọn bò ilẹ ti a fi okuta tẹ́, nwọn si tẹriba, nwọn si yìn Oluwa, wipe, Nitoriti o ṣeun; nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai.
4. Ọba ati awọn enia si rubọ niwaju Oluwa.
5. Solomoni ọba si rubọ ẹgbã-mọkanla malu ati ọkẹ mẹfa agutan: bẹ̃ni ọba, ati gbogbo awọn enia yà ile Ọlọrun na si mimọ́.
6. Awọn alufa duro lẹnu iṣẹ wọn; awọn ọmọ Lefi pẹlu ohun-ọnà orin Oluwa, ti Dafidi ọba ti ṣe lati yìn Oluwa, nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai, nigbati Dafidi nkọrin iyìn nipa ọwọ wọn; awọn alufa si fùn ipè niwaju wọn, gbogbo Israeli si dide duro.
7. Solomoni si yà arin agbala na si mimọ́ ti mbẹ niwaju ile Oluwa: nitori nibẹ li o ru ẹbọ ọrẹ sisun, ati ọra ẹbọ alafia, nitori pẹpẹ idẹ ti Solomoni ti ṣe kò le gbà ọrẹ sisun, ati ọrẹ onjẹ ati ọ̀ra na.
8. Li akokò na pẹlu Solomoni se àse na ni ijọ meje, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, ijọ enia nlanla, lati ìwọ Hamati titi de odò Egipti.
9. Ati li ọjọ kẹjọ nwọn ṣe apejọ mimọ́; nitori ti nwọn ṣe ìyasi-mimọ́ pẹpẹ na li ọjọ meje, ati àse na, ọjọ meje.