2. Kro 4:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe pẹpẹ idẹ kan, ogún igbọnwọ ni gigùn rẹ̀, ogún igbọnwọ si ni ibu rẹ̀, ati igbọnwọ mẹwa ni giga rẹ̀.

2. O si ṣe agbada didà nla, igbọnwọ mẹwa lati eti kan de eti ekeji, o ṣe birikiti, igbọnwọ marun si ni giga rẹ̀; okùn ọgbọ̀n igbọ̀nwọ li o si yi i kakiri:

3. Aworan malu si wà labẹ rẹ̀ yi i kakiri, nwọn si lọ yi agbada nla na kakiri: igbọnwọ mẹwa yi i ka, ọwọ́ meji malu li a dà ni didà wọn kan.

4. O duro lori malu mejila wọnni, mẹta nwò iha ariwa, ati mẹta nwò iwọ-õrun, ati mẹta nwò gusu ati mẹta nwò iha ilà-orun: a si gbé agbada na ka ori wọn, gbogbo iha ẹhin wọn si wà ninu.

2. Kro 4