8. Ati iyokù iṣe Jehoiakimu ati awọn ohun-irira rẹ̀ ti o ti ṣe, ti a si ri ninu rẹ̀, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Israeli ati Juda: Jehoiakini, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.
9. Ẹni ọdun mejidilogun ni Jehoiakini nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba oṣù mẹta ati ijọ mẹwa ni Jerusalemu: o si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa.
10. Ati li amọdun, Nebukadnessari ranṣẹ, a si mu u wá si Babeli, pẹlu ohun-elo daradara ile Oluwa, o si fi Sedekiah, arakunrin rẹ̀, jọba lori Juda ati Jerusalemu.
11. Ẹni ọdun mọkanlelogun ni Sedekiah, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mọkanla ni Jerusalemu.
12. O si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀, kò si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju Jeremiah, woli, ti o sọ̀rọ lati ẹnu Oluwa wá.
13. On pẹlu si ṣọ̀tẹ si Nebukadnessari ọba, ẹniti o ti mu u fi Ọlọrun bura; ṣugbọn o wà ọrùn rẹ̀ kì, o si mu aiya rẹ̀ le lati má yipada si Oluwa Ọlọrun Israeli.
14. Pẹlupẹlu, gbogbo awọn olori awọn alufa ati awọn enia dẹṣẹ gidigidi bi gbogbo irira awọn orilẹ-ède, nwọn si sọ ile Oluwa di ẽri, ti on ti yà si mimọ́ ni Jerusalemu.
15. Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn si ranṣẹ si wọn lati ọwọ awọn onṣẹ rẹ̀, o ndide ni kùtukutu o si nranṣẹ, nitori ti o ni iyọ́nu si awọn enia rẹ̀, ati si ibugbe rẹ̀.