5. Ẹ si duro ni ibi mimọ́ na, gẹgẹ bi ipin idile awọn baba arakunrin nyin, awọn enia na, ati bi ipin idile awọn ọmọ Lefi.
6. Bẹ̃ni ki ẹ pa ẹran irekọja na, ki ẹ si yà ara nyin si mimọ́, ki ẹ si mura fun awọn arakunrin nyin, ki nwọn ki o le mã ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa nipa ọwọ Mose.
7. Josiah si fun awọn enia na, ni ọdọ-agutan ati ọmọ ewurẹ, lati inu agbo-ẹran, gbogbo rẹ̀ fun ẹbọ irekọja na, fun gbogbo awọn ti o wà nibẹ, iye rẹ̀ ẹgbã mẹdogun, ati ẹgbẹdogun akọmalu: lati inu ini ọba ni wọnyi.
8. Awọn ijoye rẹ̀ si fi tinutinu ta awọn enia li ọrẹ, fun awọn alufa, ati fun awọn ọmọ Lefi: Hilkiah ati Sekariah ati Jehieli, awọn olori ile Ọlọrun, si fun awọn alufa fun ẹbọ irekọja na ni ẹgbẹtala ẹran-ọ̀sin kekeke, ati ọ̃dunrun malu.
9. Koniah ati Ṣemaiah ati Netaneeli, awọn arakunrin rẹ̀, ati Hasabiah ati Jehieli ati Josabadi, olori awọn ọmọ Lefi, si fun awọn ọmọ Lefi fun ẹbọ irekọja na ni ẹgbẹdọgbọn ọdọ-agutan, ati ẹ̃dẹgbẹta malu.
10. Bẹ̃li a si mura ìsin na, awọn alufa si duro ni ipò wọn, ati awọn ọmọ Lefi ni ipa iṣẹ wọn gẹgẹ bi aṣẹ ọba.
11. Awọn ọmọ Lefi si pa ẹran irekọja na, awọn alufa si wọ́n ẹ̀jẹ na lati ọwọ wọn wá, awọn ọmọ Lefi si bó wọn.
12. Nwọn si yà awọn ẹbọ-sisun sapakan, ki nwọn ki o le pin wọn funni gẹgẹ bi ipin idile awọn enia, lati rubọ si Oluwa, bi a ti kọ ọ ninu iwe Mose. Bẹ̃ni nwọn si ṣe awọn malu pelu.
13. Nwọn si fi iná sun irekọja na gẹgẹ bi ilana na: ṣugbọn awọn ẹbọ mimọ́ iyokù ni nwọn bọ̀ ninu ìkoko, ati ninu òdu ati ninu agbada, nwọn si pin i kankan fun gbogbo enia.
14. Lẹhin na nwọn mura silẹ fun ara wọn, ati fun awọn alufa; nitoriti awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, wà ni riru ẹbọ sisun ati ọ̀ra titi di alẹ; nitorina awọn ọmọ Lefi mura silẹ fun ara wọn ati fun awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni.
15. Awọn akọrin, awọn ọmọ Asafu duro ni ipò wọn, gẹgẹ bi ofin Dafidi, ati ti Asafu, ati ti Hemani, ati ti Jedutuni, ariran ọba; awọn adèna si duro ni olukuluku ẹnu-ọ̀na; nwọn kò gbọdọ lọ kuro li ọ̀na-iṣẹ wọn, nitoriti awọn arakunrin wọn, awọn ọmọ Lefi, ti mura silẹ dè wọn.
16. Bẹ̃ni a si mura gbogbo ìsin Oluwa li ọjọ kanna, lati pa irekọja mọ́, ati lati ru ẹbọ sisun lori pẹpẹ Oluwa, gẹgẹ bi ofin Josiah, ọba.
17. Ati awọn ọmọ Israeli ti a ri nibẹ, pa irekọja na mọ́ li akoko na, ati ajọ aiwukara li ọjọ meje.