Nitorina awọn iranṣẹ rẹ̀ gbé e kuro ninu kẹkẹ́ na, nwọn si fi i sinu kẹkẹ́ rẹ̀ keji; nwọn si mu u wá si Jerusalemu, o si kú, a si sìn i ninu ọkan ninu awọn iboji awọn baba rẹ̀. Gbogbo Juda ati Jerusalemu si ṣọ̀fọ Josiah.