1. JOSIAH si pa irekọja kan mọ́ si Oluwa ni Jerusalemu: nwọn si pa ẹran irekọja na li ọjọ kẹrinla oṣù kini.
2. O si yàn awọn alufa si iṣẹ wọn, o si gbà wọn ni iyanju si ìsin ile Oluwa.
3. O si wi fun awọn ọmọ Lefi ti nkọ́ gbogbo Israeli, ti iṣe mimọ́ si Oluwa pe, Ẹ gbé apoti-ẹri mimọ́ nì lọ sinu ile na ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israeli, ti kọ́; kì yio jẹ ẹrù li ejika mọ́: ẹ sìn Oluwa Ọlọrun nyin nisisiyi, ati Israeli, awọn enia rẹ̀;
4. Ẹ si mura nipa ile awọn baba nyin, li ẹsẹsẹ nyin, gẹgẹ bi iwe Dafidi, ọba Israeli, ati gẹgẹ bi iwe Solomoni, ọmọ rẹ̀.
5. Ẹ si duro ni ibi mimọ́ na, gẹgẹ bi ipin idile awọn baba arakunrin nyin, awọn enia na, ati bi ipin idile awọn ọmọ Lefi.
6. Bẹ̃ni ki ẹ pa ẹran irekọja na, ki ẹ si yà ara nyin si mimọ́, ki ẹ si mura fun awọn arakunrin nyin, ki nwọn ki o le mã ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa nipa ọwọ Mose.
7. Josiah si fun awọn enia na, ni ọdọ-agutan ati ọmọ ewurẹ, lati inu agbo-ẹran, gbogbo rẹ̀ fun ẹbọ irekọja na, fun gbogbo awọn ti o wà nibẹ, iye rẹ̀ ẹgbã mẹdogun, ati ẹgbẹdogun akọmalu: lati inu ini ọba ni wọnyi.
8. Awọn ijoye rẹ̀ si fi tinutinu ta awọn enia li ọrẹ, fun awọn alufa, ati fun awọn ọmọ Lefi: Hilkiah ati Sekariah ati Jehieli, awọn olori ile Ọlọrun, si fun awọn alufa fun ẹbọ irekọja na ni ẹgbẹtala ẹran-ọ̀sin kekeke, ati ọ̃dunrun malu.
9. Koniah ati Ṣemaiah ati Netaneeli, awọn arakunrin rẹ̀, ati Hasabiah ati Jehieli ati Josabadi, olori awọn ọmọ Lefi, si fun awọn ọmọ Lefi fun ẹbọ irekọja na ni ẹgbẹdọgbọn ọdọ-agutan, ati ẹ̃dẹgbẹta malu.
10. Bẹ̃li a si mura ìsin na, awọn alufa si duro ni ipò wọn, ati awọn ọmọ Lefi ni ipa iṣẹ wọn gẹgẹ bi aṣẹ ọba.
11. Awọn ọmọ Lefi si pa ẹran irekọja na, awọn alufa si wọ́n ẹ̀jẹ na lati ọwọ wọn wá, awọn ọmọ Lefi si bó wọn.