6. O si bẹ̀ ọkẹ marun ogun alagbara akọni ọkunrin lati inu Israeli wá fun ọgọrun talenti fadakà.
7. Ṣugbọn enia Ọlọrun kan tọ̀ ọ wá, wipe, Ọba, máṣe jẹ ki ogun Israeli ki o ba ọ lọ: nitoriti Oluwa kò wà pẹlu Israeli, ani gbogbo awọn ọmọ Efraimu.
8. Ṣugbọn bi iwọ o ba lọ, ma lọ, mu ara le fun ogun na: Ọlọrun yio bì ọ ṣubu niwaju ọta: Ọlọrun sa li agbara lati ṣe iranlọwọ, ati lati bì ni ṣubu.
9. Amasiah si wi fun enia Ọlọrun na pe, Ṣugbọn kili awa o ha ṣe nitori ọgọrun talenti ti mo ti fi fun ẹgbẹ-ogun Israeli? Enia Ọlọrun na si dahùn pe, O wà li ọwọ Oluwa lati fun ọ li ọ̀pọlọpọ jù eyi lọ.