2. Kro 25:14-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. O si ṣe lẹhin ti Amasiah ti ibi pipa awọn ara Edomu bọ̀, o si mu awọn oriṣa awọn ọmọ Seiri bọ̀, o si gà wọn li oriṣa fun ara rẹ̀, o si tẹ̀ ara rẹ̀ ba niwaju wọn, o si sun turari fun wọn.

15. Nitorina ni ibinu Oluwa ru si Amasiah, o si ran woli kan si i, ti o wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi nwá oriṣa awọn enia na, ti kò le gbà awọn enia wọn lọwọ rẹ?

16. O si ṣe bi o ti mba a sọ̀rọ, ọba si wi fun u pe, A ha fi ọ ṣe igbimọ̀ ọba bi? fi mọ: ẹ̃ṣe ti a o fi pa ọ? Nigbana ni woli na fi mọ; o si wipe, Emi mọ̀ pe, Ọlọrun ti pinnu rẹ̀ lati pa ọ run, nitoriti iwọ ti ṣe eyi, ti iwọ kò si tẹ eti si imọ̀ran mi.

17. Nigbana ni Amasiah, ọba Juda, gbà ẹ̀kọ, o si ranṣẹ si Joaṣi ọmọ Jehoahasi, ọmọ Jehu ọba Israeli, wipe, Wá, jẹ ki a wò ara wa li oju.

18. Joaṣi, ọba Israeli, si ranṣẹ si Amasiah, ọba Judah, wipe, Ẹgun-ọ̀gan ti o wà ni Lebanoni ranṣẹ si igi kedari ti o wà ni Lebanoni, wipe, Fi ọmọbinrin rẹ fun ọmọ mi li aya: ẹranko igbẹ kan ti o wà ni Lebanoni si kọja nibẹ, o si tẹ ẹ̀gun-ọ̀gan na mọlẹ.

19. Iwọ wipe, Kiyesi i, iwọ ti pa awọn ara Edomu; ọkàn rẹ si gbé soke lati ma ṣogo: njẹ gbe ile rẹ, ẽṣe ti iwọ nfiran fun ifarapa rẹ, ti iwọ o fi ṣubu, ani iwọ ati Juda pẹlu rẹ?

20. Ṣugbọn Amasiah kò fẹ igbọ́; nitori lati ọdọ Ọlọrun wá ni, ki o le fi wọn le awọn ọta wọn lọwọ, nitoriti nwọn nwá awọn oriṣa Edomu.

21. Bẹ̃ni Joaṣi, ọba Israeli gòke lọ; nwọn si wò ara wọn li oju, on ati Amasiah, ọba Juda, ni Bet-Ṣemeṣi ti iṣe ti Juda,

22. A si ṣẹ́ Juda niwaju Israeli, nwọn salọ olukuluku sinu agọ rẹ̀.

23. Joaṣi ọba Israeli si mu Amasiah, ọba Juda ọmọ Joaṣi, ọmọ Ahasiah ni Bet-Ṣemeṣi, o si mu u wá si Jerusalemu, o si wó odi Jerusalemu lati ẹnubode Efraimu titi de ẹnu-bode igun, irinwo igbọnwọ.

24. O si mu gbogbo wura ati fadakà, ati gbogbo ohun-elo ti a ri ni ile Ọlọrun lọdọ Obed-Edomu, ati awọn iṣura ile ọba, ati awọn ògo pẹlu, o si pada lọ si Samaria.

25. Amasiah, ọmọ Joaṣi, ọba Juda, wà li ãye lẹhin ikú Joaṣi, ọmọ Jehoahasi ọba Israeli, li ọdun mẹdogun.

2. Kro 25