2. Kro 24:25-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Nigbati nwọn si lọ kuro lọdọ rẹ̀, (nwọn sa ti fi i silẹ ninu àrun nla) awọn iranṣẹ rẹ̀ si di rikiṣi si i, nitori ẹ̀jẹ awọn ọmọ Jehoiada alufa, nwọn si pa a lori akete rẹ̀, o si kú: nwọn si sìn i ni ilu Dafidi, ṣugbọn nwọn kò sìn i ni iboji awọn ọba.

26. Wọnyi li awọn ti o di rikiṣi si i, Sabadi, ọmọ Simeati, obinrin ara Ammoni, ati Jehosabadi, ọmọ Ṣimriti, obinrin ara Moabu.

27. Njẹ niti awọn ọmọ rẹ̀, ati titobi owo-ọba, ti a fi le e lori, ati atunṣe ile Ọlọrun, kiyesi i, a kọ wọn sinu itan iwe awọn ọba. Amasiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

2. Kro 24