2. Kro 23:20-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. O si mu awọn olori-ọrọrun, ati awọn ọlọla, ati awọn bãlẹ ninu awọn enia ati gbogbo enia ilẹ na, nwọn si mu ọba sọ̀kalẹ lati ile Oluwa wá: nwọn si gbà ẹnu-ọ̀na giga wá sinu ile ọba, nwọn si gbé ọba ka ori itẹ ijọba na.

21. Gbogbo awọn enia ilẹ na si yọ̀: ilu na si tòro lẹhin ti a fi idà pa Ataliah.

2. Kro 23