17. Gbogbo awọn enia na si lọ si ile Baali, nwọn si wó o lulẹ, nwọn si fọ pẹpẹ ati awọn ere rẹ̀ tũtu, nwọn si pa Mattani alufa Baali, niwaju pẹpẹ.
18. Jehoiada si fi iṣẹ itọju ile Oluwa le ọwọ awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, ti Dafidi ti pin lori ile Oluwa, lati ma ru ẹbọ ọrẹ sisun Oluwa, bi a ti kọ ọ ninu ofin Mose, pẹlu ayọ̀ ati pẹlu orin lati ọwọ Dafidi.
19. O si fi awọn adena si ẹnu-ọ̀na ile Oluwa, ki ẹni alaimọ́ ninu ohun-kohun ki o má ba wọ̀ ọ.
20. O si mu awọn olori-ọrọrun, ati awọn ọlọla, ati awọn bãlẹ ninu awọn enia ati gbogbo enia ilẹ na, nwọn si mu ọba sọ̀kalẹ lati ile Oluwa wá: nwọn si gbà ẹnu-ọ̀na giga wá sinu ile ọba, nwọn si gbé ọba ka ori itẹ ijọba na.
21. Gbogbo awọn enia ilẹ na si yọ̀: ilu na si tòro lẹhin ti a fi idà pa Ataliah.