O si wò, si kiyesi i, ọba duro ni ibuduro rẹ̀ li ẹba ẹnu-ọ̀na, ati awọn balogun ati awọn afunpè lọdọ ọba: ati gbogbo awọn enia ilẹ na si yọ̀, nwọn si fun ipè, ati awọn akọrin pẹlu ohun-elo orin, ati awọn ti nkede lati kọ orin iyin. Nigbana ni Ataliah fa aṣọ rẹ̀ ya, o si wipe: Ọ̀tẹ! Ọ̀tẹ!