2. Kro 22:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN olugbe Jerusalemu, si fi Ahasiah, ọmọ rẹ̀ abikẹhin, jọba ni ipò rẹ̀: nitori awọn ẹgbẹ́ ogun, ti o ba awọn ara Arabia wá ibudo, ti pa gbogbo awọn ẹgbọn. Bẹ̃ni Ahasiah, ọmọ Jehoramu, ọba Juda, jọba.

2. Ẹni ọdun mejilelogun ni Ahasiah, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun kan ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Ataliah, ọmọbinrin Omri.

3. On pẹlu rìn li ọ̀na Ahabu: nitori iya rẹ̀ ni igbimọ̀ rẹ̀ lati ṣe buburu.

2. Kro 22