Nigbana ni Jehoramu rekọja lọ pẹlu awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo kẹkẹ́ rẹ̀ pẹlu rẹ̀: o si dide li oru, o si kọlù awọn ara Edomu ti o ká a mọ, ati awọn olori kẹkẹ́.