2. Kro 2:13-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Njẹ nisisiyi emi rán ọkunrin ọlọgbọ́n kan, ti o mọ̀ oye, ani Huramu-Abi,

14. Ọmọ obinrin kan ninu awọn ọmọbinrin Dani: baba rẹ̀ si ṣe ọkunrin ara Tire ti o gbọ́ngbọn ati ṣiṣẹ ni wura, ati ni fadakà, ni idẹ, ni irin, ni okuta, ati ni ìti-igi, ni èse-aluko, ni alaró, ati ni ọ̀gbọ daradara, ati òdodó, lati gbẹ́ oniruru ohun gbigbẹ́ pẹlu, ati lati ṣe awari ìmọ ẹrọ gbogbo ti a o fi fun u ṣe, pẹlu awọn ọlọgbọ́n rẹ, ati pẹlu awọn ọlọgbọ́n oluwa mi Dafidi, baba rẹ.

15. Njẹ nitorina alikama ati ọkà barli, ororo, ati ọti-waini na ti oluwa mi ti sọ, jẹ ki o fi ranṣẹ si awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀.

16. Awa o si ké igi lati Lebanoni wá, iyekiye ti iwọ o fẹ; awa o si mu wọn fun ọ wá ni fifó li okun si Joppa; iwọ o si rù wọn gòke lọ si Jerusalemu.

17. Solomoni si kaye gbogbo awọn ajeji ọkunrin ti o wà ni ilẹ Israeli, gẹgẹ bi kikà ti Dafidi, baba rẹ̀ ti kà wọn; a si ri pe, nwọn jẹ ọkẹ-mẹjọ o di-egbejilelọgbọ̀n.

2. Kro 2